Oríṣimẹta ẹ'dá làá pàdé arìnrìn-àjò
Oríṣimẹta ẹ'dá làá kán l'óde ayé ẹni're
Ẹní tí o gbé ní sókè, ìyẹn a tàn bí ọjọ' túntún
Ẹní tí o b'ẹni kẹ́dùn kìí jìnà sí'bí ófọ
Ẹní tí o lóṣo ìdènà, ìyẹn kì má i fojú hàn 'ní
K'inú rẹ mà ṣo ẹ ẹni're
K'ọwọ ẹ mà ri're àti ìbùkún
Àní, k'òrí ẹ gbé ẹ dé'bi ayọ, òun ní Bàbá wi
Àṣẹ gùn! (Bẹẹni)
Oríṣimẹta ẹ'dá làá pàdé arìnrìn-àjò
Oríṣimẹta ẹ'dá làá kán l'óde ayé ẹni're
Ẹní tí o gbé ní pọn s'ẹ'yìn g'òkè láìkùn, lai ṣ'awawi
Ẹní tí o kò ní l'ẹsẹ bí itakun arapalakiri
Ẹní tí o wọ ní s'ọ̀gbun ìjọgbọ, àgbàrá olóríkúnkún
K'inú rẹ mà ṣo ẹ, ẹni're
K'ọwọ ẹ mà ri're àti ìbùkún
Àní, k'òrí ẹ gbé ẹ dé'bi ayọ, òun ní Bàbá wi
Àṣẹ gùn! (Aṣẹ dẹ tí gùn náàní)
Oríṣimẹta ẹ'dá làá pàdé arìnrìn-àjò
Oríṣimẹta ẹ'dá làá kán l'óde ayé ẹni're
Ẹní tí o bà ní s'ọrọ tútù, a fi'nù hàn ní
Ẹní tí o tọ ní s'ọnà ìyà, òun kẹ, à gbà 'bomiran
Ẹní tí o bà ní ṣé pọ, à gb'ẹyín ṣé yeye ẹní
K'inú rẹ mà ṣo ẹ ẹni're
K'ọwọ ẹ mà ri're àti ìbùkún
Àní, k'òrí ẹ gbé ẹ dé'bi ayọ, òun ní Bàbá wi
Àṣẹ gùn, àṣẹ gùn (aṣẹ dẹ tí gùn)
K'inú rẹ mà ṣo ẹ ẹni're
K'ọwọ ẹ mà ri're àti ìbùkún
Àní, k'òrí ẹ gbé ẹ dé'bi ayọ, òun ní Bàbá wi
Àṣẹ gùn
Ọrẹ wá, ọrẹ wá, mà lọ jẹjẹ
Aṣẹ dẹ tí gùn náàní, má lọ
Kò sí ẹwu kánkán, kò sí ẹwu lọ'nà
Málọ, málọ jẹjẹ, jẹjẹ, málọ
Jẹjẹ, jẹjẹ
Àní, fọkàn balẹ, má lọ